B'ójútirí
Lẹ'nú wí,
B'ẹiyẹ oko rí
Gbogbo etí oko
Pàtàpàtà ní'gbọ
B'orẹẹ odo ri,
A ke sí-o sí-o
B'ewúrẹ bà rí,
A ke mẹẹ-meẹ
B'àgùntàn rí tí ẹ
A fí igbe ìbosí sẹ'nu. (11)


Ùn bí ohún ojú rí
Lẹ'nu ng sọ
Kí se bí tí èèwọ
Bí ọbà bá sọ tán
Ìwọfa àsí sọ tiẹ lẹyìn
Ọrọ ẹnu dúníyàn dàbì
Kànnàkánnán tí à ng tá ní ìjù
Ẹnu omo aráye o mọn
Bí wọn ng se kọ isẹ tí ẹ
À ní ko'rí ẹní o màsùn
Kí ẹlẹda ẹní o mà sì togbe. (22)


Ohun tí mo mọn ní pe,
Orí tí yío d'ade lọla
Lèè mà sùn orí ẹní loní
Wọn ní ìbí kìí jù 'bí
Ìbí tí à bí erú là bí omo
Ng bí bo tí wú àsẹdá ní pínín
Kosí ẹdá tí lèé fí làkàye sọ
Ìye ọsàn tí ẹyọ omo rẹ kàn
Yio o dà bí à bá fí bọ ílẹ ọlọrà
Gbogbo wá kúkú lá ng gbíyànjú
Ko sí ẹní gbàdúrà ko bí'mọn ọlẹ. (33)


Sugbọn ẹnu ẹníyàn ní'soro
Ọmo ádámọn I bá yè fẹ'nu
Fá bí ígbín, aiye I ba rọrùn
Omo ẹnìyàn ì bá yè fí orí kìrí
Bí omo ebí ng pá l'ẹyìn iya ẹ
Wọn I ba ṣ'ahọn ni dede ẹnu
Àgbà-àgbà níkàn ní à bá bẹ
Bí à bá rí eyí tí àsẹ nínú wọn
Kí o má sàlaí foríjìn wá
Torí bopẹ-boyá, ohún to pẹ
Dàndàn yio padà dí ìre. (44)